Breaking News

Damasus, Omotola, Ezekwesili, Funmi Iyanda dá sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo

Ọmọtọla EkeindeImage copyright@OMOTOLAFANS
Àkọlé àwòránNínú fídíò kan tó ń ja rànyìnrànyìn ni ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ yìí ti kọ́kọ́ gbèrú
Ikanni ayelujara ṣi n rọ kẹkẹ bayii lori ẹsun ifipabanilopọ ti iyawo gbajugbaja onkọrinTimi Dakolo, Busọla Dakolo fi kan pasitọ agba ijọ COZA, Biọdun Fatoyinbo.
Oniruuru ọrọ ni awọn eekan pẹlu n sọ lori rẹ lori oju opo twitter, Facebook, Instagram atawọn ọpọ miran, yala lati gbe sẹyin Busọla aya Dakolo abi Pasitọ Biọdun Dakolo
Lara awọn to ti sọrọ ni Funmi Iyanda, gbajugbaja agbohunsafẹfẹ to ni oun gba gbogbo ọrọ ti Busọla sọ lai ku ẹyọkan gbọ ati pe ireti oun ni pe ẹwọn lo yẹ ki atubọtan iranṣẹ Ọlọrun naa jẹ.
Bakan naa ni gbajugbaja oṣere tiata, Ọmọtọla Jalade Ẹkẹinde naa sọ tirẹ si iroyin naa eleyii to ti ni iṣoro to n koju awọn to foju wina iṣẹlẹ ifipabanilopọ ni ọna ati fi idi ẹsun wọn mulẹ.
O wa rọ gbogbo awọn ti irufẹ iṣẹlẹ bayii ti ṣẹ si lati ọdọ iranṣẹ Ọlọrun naa bọ si gbangba lati wa wi tẹnu wọn
Media captionKayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá
Ni tirẹ, eekan oloṣelu, Abikẹ Dabiri-Erewa to jẹ alaga ajọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria loke okun naa ti ṣe afihan atilẹyin rẹ fun Busọla bẹẹni o kan sara si iyawo iransẹ Ọlọrun naa gẹgẹ bii obinrin to lọkan akin ati igboya pẹlu iroyin ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi n kan ọks rẹ lọpọ igba bayii.
Ninu ọrọ tirẹ, minisita lorilẹ-ede Naijiria nigbakan ri, Oby Ezekwesili pẹlu kọminu lori iroyin ọhun.
"Ohun ti mo ka bani ninu jẹ pupọ. Mo gbadura fun iwosan... mo rọ iranṣẹ Ọlọrun yii lati tete dahun si ẹsun nla wọnyii. Ni kiakia,"
Stella Damasus to jẹ gbajugbaja oṣere naa ti jade bere ibeere nla pe ṣe awọn eeyan ko ṣì tii gba ọrọ ẹsun yii gbọ?

O ni oun ṣẹṣẹ ba ẹlomii ti o fẹsun kan Fatoyinbo pe o tun fipa ba oun lo pẹ sọrọ tan ni o

No comments