Breaking News

COZA: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ni ṣọ́ọ́ṣì COZA láàrọ́ yìí

Modele ati Biodun FatoyinboImage copyrightINSTAGRAM/MODELE FATOYINBO
Saaju ni Busola Dakolo aya gbajugbaja olorin Timi Dakolo fẹsun kan Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti ijọ COZA pe o fipa ba oun lo pọ nigba kan.
Lẹyin eyi ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria sọrọ sita pe iwa ifipabanilopọ gbọdọ di ohun igbagbe ni awujọ wa.
Pasito Biodun Fatoyinbo to da ijọ COZA silẹ fi atẹjadee sita pe irọ ni ẹsun naa nitori oun ko fipa ba ẹnikẹni lo pọ ri laye ounCOZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo.
coza
Àkọlé àwòránAwon obinrin ti n pe siwaju ijo COZA
Awọn obinrin ti pejọ pọ siwaju ijọ COZA ni Guzape ni Asokoro ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria fún iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ.
coza
Àkọlé àwòránPasito kuro nipo re
Ni ipinlẹ Eko, awọn eniyan ti n korajọ pọ lati ṣe iwọde lodi si ifipabanilopọ.
Opopona Mobolaji Bank Anthony ti ijọ COZA wa ni ipinlẹ Eko ni wọn pejọ pọ si fi n ṣe iwọde pe ko yẹ ki a gbọ iru eyi ninu ijọ Olorun.
coza
Àkọlé àwòránNi ipinlẹ Eko, awọn eniyan ti n korajọ pọ lati ṣe iwọde lodi si ifipabanilopọ
Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko.
coza
Àkọlé àwòránAw#on agbofinro lo duro senu ona soosi COZA ni Eko
Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko
Ojo ti bẹrẹ ni Ikeja nibi ti awọn eniyan ko ara wọn jọ si lati ṣe iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ adari ijọ COZA.
coza
Àkọlé àwòránPelu ojo to n ro naa ni awon eniyan si duro si fun iwode naa
Gbogbo awon to jade ninu ojo ni Eko n pariwo 'No to Rape' ni.
coza
Àkọlé àwòránAriwo "No to Rape" ni wọn n pa ni iwọde ipinlẹ Eko
Ariwo " No to Rape" ni àwọn olùwọ́de ń pa nipinlẹ Eko nínú òjò.
coza
Àkọlé àwòránAwon eniyan kan n satileyin fun Busola Dakolo
Ero pupọ lo ti kun ita ile ijọsin Commonwealth of Zion Assembly nipinlẹ Eko.
Iroyin to n kan BBC lọwọ ni pe awọn ọmọ ijọ COZA nikan ni wọn n jẹ ko wọle inu ile ijọsin laarọ yii lati jọsin.

No comments