Breaking News

Awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria mẹ́rìndínlọ́gbọ̀nlelọ́ọ̀dúnrún ni NEMA gba silẹ lati Libya


Awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria mẹ́rìndínlọ́gbọ̀nlelọ́ọ̀dúnrún ni NEMA gba silẹ lati Libya
Ajo to n mojuto isẹlẹ pajawiri lorile ede Naijiria (National Emergency Management Agency ,NEMA)  ti ni  ọmọ orilẹ ede Naijiria ti iye won le ni mẹ́rìndínlọ́gbọ̀nlelọ́ọ̀dúnrún to wa ni orile ede Libya, to jẹ pe won ko ri owo lati fi pada sorile ede mọ, ni ijoba ti nawọ iranwọ si lati da wọn pada sorilẹ ede yii.
Alakoso ajo NEMA to wa ni ipinlẹ Eko, Idris Muhammed ni o soju abẹ nikoo lọjọ Ẹti, lasiko to n ba awon akoroyin soro .
Muhammed  ni awon omo orile ede Naijiria yoo maa de si papa ofurufu orile ede Naijiria pelu balu orisi meji.
O ni ọna meji ni won da awon eniyan naa si, o ni  balu akọkọ ko iye awon eniyan ti iye won jẹ mẹ́tàlélógóje de si orile ede Naijiria ni deede aago mẹ́wàá kọja ogún isẹju, lọjọBọ.
Muhammed ni ajo  agbaye to n ri si bi awon eniyan se n lọ lati orile ede kan si omiran (International Organisation for Migration IOM)ati ajo European Union (EU )pelu iranwo awon egbe ti  ki i se ti ijoba (Voluntary Returnees ,AVR) lo ko awon eniyan naa wa si orile ede Naijiria.
O ni lara awon ile-ise ati ajo to wa nikalẹ lasiko ti awon eniyan naa de si orile ede Naijiria ni , ajo to n ri si wiwọle ati jijade lorile ede Naijiria,(Nigeria Immigration Service)ile-ise to n mojuto papa ofurufu(Federal Airports Authority of Nigeria) ati ajo to n gbogun ti fifi omo se okoowo.  
O ni “awon eniyan ti won ko wa lati orile ede Libya jẹ obinrin méjídínláàdọ́jọ , ti awon odomobinrin si jẹ  mẹ́fà , ọmọbinrin màrúndínlógún  , gbogbo iye won jẹ mọ́kàndínláàdọ́sàn án .“
O  wa ro awon eniyan ti wọn ko pada wa si orile ede  Naijiria  lati fowosowopo pelu  ijoba , ni eyi ti idagbasoke yoo se de ba orile ede Naijiria.
 Muhammed ni : “Ipinnu wa fun orile ede Naijria ,ti n wa si imusẹ bayii. Bi ẹ se n gbiyanju lati sa kuro lorile ede yii, ni awon kan naa n gbiyanju lati sa kuro lati ilẹ okeere wa si orile ede Naijiria.
“Lati kuro ni orile ede kan si omiran , jẹ ohun to dara , ko si eni to ni ki ẹ maa kuro lọ si orile ede  miiran ,sugbon ki e wa maa gba ọna ẹburu , inu igbo kiji-kiji ,ko dara rara.
“Ipinnu ijọba apapọ ni lati je ki gbogbo omo orile ede Naijiria ko ipa tirẹ lati mu idagbasoke ba orile ede yii.
“ Ẹ jẹ ki gbogbo wa duro si orile ede yii , ki a se atileyin fun ijoba lati mu idagbasoke ba orile ede Naijiria.
“A ni igbagbo ninu ijoba yii pe, won yoo mu wa de ebute ogo, sugbon ẹyin ọdọ  orile ede yii ni irinsẹ fun idagbasoke orile ede Naijiria.
NEMA tẹwọgba awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria to le ni mẹ́rìndínlọ́gbọ̀nlelọ́ọ̀dúnrún lati orile ede Libya.

No comments