Breaking News

Awon adari orile ede Afrika ki aare Buhari ku ori -ire

Opolopo awon adari  orile ede Afirika ni won ti n fiwe ati ipe ranse si aare Buhari lati ki Buhari ku ori ire fun jijawe olubori gege bi aare orile ede Naijiria fun saa keji.
Oba Mohammed V1 ti orile ede Morocco tun sapejuwe aseyori aare Buhari gege bi eni ti awon omo orile ede Naijiria ni igbekele ninu rẹ.Oba naa wa seleri lati se ise pelu aare lona ti eto idagbasoke yoo se deba  orile ede mejeeji naa.
Oba Mohammed so pe‘Jijawe olubori gege  bi aare orile ede Naijiria fun igba keji jẹ igbekele ti awon omo orile ede Naijiria ni ,ninu ijoba aare Buhari, paapaa julo lori eto okoowo, eto aabo ati  isejọba.’’
Oba naa wa fi idunnu re han nipa ibasepo to wa laarin orile ede Naijiria ati orile ede Naijiria.
O ni orile ede Morocco yoo  tepele  mọ ipinnu re lati tubo fowosowopo pelu aare orile ede Naijiria lati mu  eto idagbasoke ba orile ede mejeji ohun , ni eyi ti orile ede mejeeji naa yoo se jẹ awokọse ni orile ede Afirika.
Orile ede Guinea
Aare orile ede Guinea ,Alpha Omar Conde naa ti ki aare Buhari ku ori ire fun jijjawe olubori gege bi aare orile ede Naijiria fun saa keji .O sapejuwe aseyori yii gege bi ireti nla fun orile ede Afirika.
Ojogbon Conde ni pe oun ni igbagbo pe, ibasepo to wa laarin orile ede Naijiria ati Guinea yoo tun tubo tesiwaju si i.
Niger/Ghana/Senegal
Saaaju eyi,ni  aare Mahamadou Issoufou ti orile ede Niger,to jẹ eni akọkọ ti o fi ipe ransẹ si aare Muhammadu Buhari lati ki ku ori ire, leyin ti ajo eleto idibo INEC ti kede rẹ gege bi eni ti o jawe olubori ninu eto idibo aare odun 2019, o ni oun yoo nifẹẹ lati tubọ maa se isẹ papọ pelu adari orile ede Naijiria , ni eyi ti, yoo tun jẹ ki ibasepo to mọnyan lori wa laarin orile ede Naijiria ati Niger.
Aare  Buhari tun ti gba iwe ẹ ku ori ire lati ọdọ awon aare orile ede bi i aare Nana Koffi-Addo ti Ghana ati Macky Sall ti orile ede Senegal.

No comments